Hymn 134: Oh from the Island bank

Lati erekusu

  1. Lati erekuṣu
    De ikangun okun,
    K’ọba juba Jesu,
    Ki nwọn mu ọrẹ wá.
    Ki Arab lé
    Orin orun;
    K’Afrik dapọ
    Gbe ‘yin Rẹ̀ ga.

  2. Ọm’ alade y’o sìn,
    Nwọn o mu ọrẹ wá:
    Lati yin agbara
    Immanuel Ọba;
    Ilẹ̀ jijin
    Yio jọsìn;
    Aiye y’o gbà
    Aṣẹ Rẹ̀ gbọ. Amin.