- f Lọ wasu ihinrere mi,
Mu gbogbo aiye gb’ ore mi;
Ẹnit’ o gb’ ọ̀rọ mi y’o là,
Ẹnit’ o kọ yio ṣegbe.
- Emi o f’ oye nla hàn nyin,
Ẹ o f’ ọ̀rọ otọ mi hàn;
Ni gbogb iṣẹ ti mo ṣe,
Ni gbogbo iṣẹ t’ ẹ o ṣe.
- Lọ wò arùn, lọ j’oku nde,
F’ orukọ mi l’ Eṣu jade;
Ki woli mi màṣe bẹ̀ru,
Bi Griki ati Ju kẹgan.
- Kọ gbogbo aiye l’ aṣẹ mi,
Mo wà lẹhin nyin de opin;
Lọwọ mi ni gbogbo ipa,
Mo le pa, mo si le gbala.
- Imọlẹ si ràn yi i ka,
Ogo nla l’ o fi lọ s’ ọrun;
Nwọn si mu de ilẹ jijin,
Ihin igoke Ọlọrun. Amin.