Hymn 131: Thou, whose almighty word

Iwo ti okunkun

  1. f Iwọ ti okunkun
    Gb ọrọ agbara Rẹ,
    cr T’ o si fọ lọ,
    p Gbọ ti wa, a mbẹ Ọ ,
    Nibit’ Ihinrere
    Kọ ti tan mọle rẹ,
    f K’ imọlẹ wa.

  2. mf ‘Wọ t’ iyẹ apa Rẹ
    Mu iriran w’ aiye,
    cr At’ ilera :
    p Ilera ti inu;
    Iriran ti ọkan ;
    Fun gbogbo enia,
    f K’ imọlẹ wa.

  3. mpIwọ Ẹmi otọ ,
    Ti o nf’ iye fun wa,
    cr Fo kakiri :
    Gbe fitila anu,
    p Fo ka oju omi,
    Nibi okunkun nla,
    fK’ imọlẹ wa.

  4. fMẹtalọkan Mimọ,
    Ọgbọn, Ifẹ , Ipa,
    Alabukun !
    ffB’ igbi omi okun
    Ti nyi ni ipa rẹ,
    Bẹ ka gbogbo aiye,
    K imọlẹ wa. Amin.