Gbọ orin ‘yin dida’ aiye, T’ẹgbẹrun orilẹ nkọ, Orin didun bi t’angẹli, O ndún bi omi pupọ --- “Bukun, ogo, ipa, ‘gbala Fun Ọlọrun lor’itẹ, Baba, Ọmọ, Ẹmi, Mimọ Ọlọla ‘lainipẹkun.”
Titi lọ, lat’orọ d’alẹ, Lor’olukuluku ‘lẹ, Lat’ ọpọlopọ enia’ Ilu alawọ pupa, ‘Lawọ dudu t’ a da n’ ide , Funfun ti o pọ niye, De ‘ le awọn Arabu.
Lati ebutẹ otutu De ilẹ ti o morun, Lẹba okun pasifik, Lat’ọpọ aimoye ọkan Onigbagbọ alayọ , Awọn to nsọna bibọ Rẹ, Nwọn fẹfẹ de sion na.
Akojọ orilẹ-ede, Lat’inu ẹya ahọn, Gbọ, nwọn nkọrin iyin titi, Gbọ orin ologo ni, O b’ afonifoji mọlẹ, O si ndun lori oke, O ndun siwaju tit’o fi Kun ibugbe Ọlọrun.
Gbọ, didun orin na dapọ Mọ orin awọn t’orun, Awọn t’o kọja n’ nu ‘ danwo Sinu isimi loke, Nwọn nfi duru kọ Hosanna, Ni’waju Ọlọrun wọn.
“ Ogo fun Ẹnt’ o fẹ wa, T’ o wẹ wa n’nu ẹjẹ Rẹ, K’ọba, alufa, ma kọrin Si Baba, Ọlọrun wa. K’ enia mimọ on Angẹli, Kọ Alleluia titi : A ṣegun ọrun aradi : Olodumare jọba. “ Amin.