- mp Orùn fẹrẹ̀ wọ̀ na,
Ọjọ lọ tan;
cr K’ ifẹ k’o ji dide
K’o rubọ aṣalẹ.
- pp Bi Jesu lor’ igi
Ti tẹriba,
T’o jọwọ ẹmi Rẹ̀
Le Baba Rè lọwọ;
- mf Bẹ ni mo f’ ẹmi mi
Fun l’afuntan,
Nipamo Rẹ̀ mimọ
L’ẹmi gbogbo sa wà.
- mp Njẹ emi o simi
Lọdọ Rẹ̀ jẹ;
Laijẹ k’ero kanṣo
Yọ ọkàn mi l’ẹnu.
- ‘Fe Tirẹ̀ ni ṣiṣe
L’ọnakona:
Mo d’oku s’ara ni,
Ati s’ohun gbogbo.
- mf Bẹl’ emi yè: ṣugbọn
Emi kọ, On
Ni mbe laye n’nu mi,
L’agbara ifẹ Rẹ̀.
- f Mẹtalọkan Mimọ
Ọlọrun kan,
L’ai ki ‘m sa jẹ Tirẹ̀,
K’On jẹ t’emi titi. Amin.