- f Ọlọrun, gbogbo araiye
Ni ẹda ọwọ Rẹ;
Ati ni iṣẹ Rẹ t’a nri
Ogo didan Rẹ ntàn.
- Ṣugbọn ifẹ nla Rẹ ti ràn
Ihinrere s’aiye;
Ti nfi ọ̀rọ ore nla hàn,
T’ o ti fi ṣe ‘ṣura,
- ‘Gbawo n’ihin yi yio tàn
Yi gbogbo aiye ká,
Ti gbogbo ẹ̀ya at’ ọkàn
Yio gbọ́ iro na?
- ‘Gbawo ni ọmọ Afrika
Y’o m’ adùn ọ̀rọ na;
At’ awọn t’ o ti s’ẹrú pẹ,
Yio di omnira?
- ‘Gbawo ni awọn keferi
T’ o wà ni okunkun;
Yio joko l’ẹsẹ Jesu,
Lati kọ́ ore Rẹ?
- Oluwa bukun fun iṣẹ
Itanka ọ̀rọ Rẹ;
K’ o si kọ ‘le iyin Rẹ le
Itẹ ẹ̀ṣẹ t’ o wó. Amin.