- Ẹni t’ o joko lọw’ ọtun
Ti Baba l’ oke ọrun,
On na l’o si mbẹbẹ fun wa
Nitori k’ a ba lè la.
- O mbẹbẹ, k’ a ab lè gba wa
Lọwọ Oludanwo nì;
Ati n’nu ẹ̀ṣẹ, on ‘binu
At’ idajọ ti mbọwá.
- O mbẹbẹ k’ a ba lè jogun
Ilẹ ti Ọba ọrun;
Tani l’ aiye, t’ o lè rohin
Ogo ati ọla na.
- On nikan ni Alagbawi
Fun awọn ẹni Tirẹ̀;
Ẹjẹ ẹnikẹni kò lè
Pa igbese t’ a jẹ ré.
- Iwọ nikan l’ Ọmọ Baba
Iwọ l’Ọba titi lai;
Enia j’ẹlẹṣẹ pupọ;
Angẹli ni ‘ranṣẹ Rẹ̀.
- Iwọ si jẹ Olododo
T’ o pé lọdọ Baba Rẹ;
Bẹ gẹgẹ ni orukọ Rẹ
Gbogbo ileri y’o ṣẹ. Amin.