Hymn 127: Speed Thy servants, Saviour, speed them;

Sin awon onse Re, sin won

  1. mf Sìn awọn onṣẹ Rẹ, sìn wọn:
    ‘W’Ọba ẹfufu, ìgbi;
    A dè wọn, O dá wọn silẹ;
    Nwọn nlọ ‘da ẹru n’idè:
    cr Wà pelu wọn, Wà pẹlu wọn,
    Apa Rẹ l’o le gbala.

  2. Nwọn f’ile at’ọrẹ́ silẹ,
    Bi aṣẹ Rẹ Oluwa;
    N’ilẹ ati loju omi,
    Jẹ́ Alafẹhinti wọn;
    cr Jọ pẹlu wọn: Jọ pẹlu wọn:
    Si ma tọ́ wọn lailewu.

  3. mp ‘Biti ‘ṣẹ wọn ko m’eso wa,
    To dabi ‘ṣẹ wọn j’asan;
    Sunmọ wọn l’anu Rẹ, Jesu,
    Mu ireti wọn duro;
    Ràn wọn lọwọ, Ràn wọn lọwọ,
    K’itara wọn tun sọji.

  4. mf N’nu ọpọlọpọ iṣoro,
    K’ wọn gbẹkẹle Ọ Jesu;
    Gbat’ iṣẹ na ba si ngbilẹ,
    Ki nwọn maṣe gberaga;
    cr Má fi wọn ‘lẹ, Má fi wọn ‘lẹ,
    Titi nwọn o r’oju Rẹ.

  5. f Nibiti nwọn o f’áyọ̀ ká
    Nibiti irugbin aiye;
    Nibiti nwọn o wà titi,
    Lọdọ Olupamọ wọn:
    Pẹlu ‘ṣẹgun, Pẹlu ‘ṣẹgun,
    Nwọn o ma kọrin Jesu. Amin.