Hymn 126: The Lord God has made Jesus Christ

Olorun ti fi Jesu se

  1. f Ọlọrun ti fi Jesu ṣe
    Etutu fun ẹ̀ṣẹ;
    On na l’ ọkàn mi duro tì,
    Ninu igbagbọ mi.

  2. p Ọlọrun si ni iyọnú
    Si ẹjẹ Ọmọ Rẹ̀;
    p Ọmọ si ti mu ẹjẹ nà
    Wọ ibi mimọ́ lọ.

  3. Nibẹ ni ẹjẹ ibuwọn
    Nsọrọ rere fun wa;
    Nibẹ ni turari didun
    Ti Alufa nla wà.

  4. f Angẹli nwo, ẹnu yà wọn;
    p Nwọn si ntẹri wọn ba
    Nitori anu Ọlọrun
    T’o f’ẹjẹ gba ni là.

  5. Emi o ma fi igbagbọ
    Sunmọ ‘bi mimọ́ yi;
    Ngo ma kọrin s’ Olugbala,
    Ngo bẹ k’o gb’ọkàn mi.

  6. A ya orin mi si mimọ,
    Nipa ẹjẹ Rẹ̀ na;
    O si dùn nipa igbagbọ,
    O jẹ ‘tọwò ọrun. Amin