- f Ma ṣiṣẹ lo, máṣe ṣarẹ̀,
Fi ayọ̀ ṣiṣẹ Baba rẹ;
Bayi ni Jesu ṣe l’ aiye,
Ko ha ye, k’ awa ko ṣe bẹ?
- f Ma ṣiṣẹ lọ, lojojumọ,
p Okunkun aiye fẹrẹ de;
f Mura si ‘ṣẹ, màṣe ṣ’ọlẹ,
Ko ba lè gba ọkan rẹ là.
- p Pupọ pupọ l’ awọn t’ o kú
Ti nwọn kò m’ ireti ọrun;
Gbe ina ‘gbagbọ rẹ, ma fi,
Ma fi si okunkun aiye.
- f Ma ṣiṣẹ lọ, ma yọ̀ pẹlu,
Lẹhin iṣẹ ‘wọ o simi;
O fẹrẹ gbohun Jesu na,
ff Y’o ke tantan pe, “Emi de.” Amin.