- Ilu t’o dara pọ̀ l’aiye;
Bẹtlẹhẹm, ‘wọ ta wọn yọ;
Ninu rẹ l’Oluwa ti wá
Lati jọba Israel.
- Ogo ti irawọ ni ju
Ti orùn owurọ lọ;
Irawọ t’ o kede Jesu
Ti a bi ninu ara.
- Awọn ‘lọgbọn ila-orùn
Mu ‘yebiye ọrẹ wá;
Ẹ wò, bi nwọn t fi wura,
Turari, ojia fun.
- Jesu, ‘Wọ ti keferi nsin
Li ọjọ ifihan Rẹ;
Fun Ọ, Baba l’a f’ogo fun,
Ati fun Ẹmi Mimọ́. Amin.