- mf Baba ọrun! Emi fẹ wà
N’ iwa mimọ́, l’ododo:
Ṣugbọn ifẹ ẹ̀ran-ara
Ntan mi jẹ nigbagbogbo.
- p Alailera ni emi ṣe,
Ẹmi mi at’ ara mi;
Ẹṣẹ ‘gbagbogbo ti mo nda
Wọ̀ mi l’ ọrùn b’ ẹrù nla.
- Ofin kan mbẹ li ọkàn mi
‘Wọ papa l’ o fi sibe;
‘Tori eyi ni mo fi fẹ
Tẹle ‘fẹ at’ aṣe Rẹ.
- Sibẹ bi mo fẹ ṣe rere,
Lojukanna mo ṣinà;
Rere l’ọrọ Rẹ i ma sọ;
Buburu l’emi si nṣe.
- Nigba pupọ ni mo njọwọ
Ara mi fun idanwò;
Bi a tilẹ̀ nkilọ fun mi
Lati gafara f’ẹṣẹ.
- Baba ọrun, Iwọ nikan
L’o to lati gba mi là;
Olugbala ti o ti ran,
On na ni ngo gbamọra.
- Fi Ẹmi Mimọ́ Rẹ tọ́ mi
S’ọnà titun ti mba gbà,
Kọ̀ mi, ṣọ mi, k’o si tọ́ mi
Iwọ Ẹmi Ọlọrun. Amin.