- f Ẹlẹṣẹ, wà sọdọ Jesu
Eni t’o wà gba ọ là;
Ẹni t’o gbe ara rẹ wọ̀
Lati rù irora rẹ.
- Olodumare ni Ẹni
T’ o fi ẹmi Rẹ̀ fun ọ;
Ọrun at’ aiye y’o kọja
Ṣugbon On wà titi lai.
- Ki ọjọ aiye rẹ to pin,
p K’ iku to p’ oju rẹ de,
f Yara, wá Olugbala rẹ,
K’ akoko na to kọja.
- Gbọ́ b’ ohùn Rẹ̀ ti nkepè ọ,
ff “Ẹlẹṣẹ wá sọdọ Mi
Ko ẹrù rẹ na tọ Mi wá;
Gbagbọ, reti, má bẹ̀ru.” Amin.