Ọlọrun mi bojuwò mi F’iyanu ‘fe nla Rẹ hàn mi; Ma jẹ ki ngberò fun ‘ra mi, ‘Tori ‘Wọ ni ngberò fun mi; Baba mi, tọ mi l’aiye yi, Jẹ ki ‘gbala Rẹ to fun mi.
Ma jẹ ki mbù le Ọ lọwọ, ‘Tori ‘Wọ li onipin mi; Ṣ’ eyi ti ‘Wọ ti pinnu rẹ́, f Iba jẹ pọnju tab’ ogo. Baba mi, &c.
Oluwa tal’o ridi Rẹ, Iwọ Ọlọrun ologo? Iwọ l’ẹgbẹgbẹrun ọna, Nibi ti nko ni ‘kanṣoṣo. Baba mi, &c.
B’ ọrun ti ga ju aiye lọ Bẹni ‘rò Rẹ ga ju t’emi; Mà dari mi k’emi lè lọ S’ ipa ọna odod Rẹ. Baba mi, &c. Amin.