mf Oluwa y’o ti pẹ to Ti ‘Wọ o tun pada; p Arẹ̀ fẹrẹ mu wa tan, Bi a ti nwọna Rẹ; Oluwa, y`o ti pẹ to Ta o ma reti Rẹ? Ọpọ ni kò gbagbọ mọ Pe ‘Wọ o tun pada.
Oluwa y’o ti pẹ to Ti ‘Wọ o kesi wa? Ti awa, ti nreti Rẹ Yio ri Ọ l’ayọ̀? Ji, wundia ti o sùn, Lọ kede bibọ Rẹ̀ Ki gbogbo awọn t’o sùn Lè mọ̀ pe O mbọ wá.
f Dide, tan fitila rẹ, Gbe ẹwù mimọ́ wọ̀, Mura lati pade Rẹ̀, ‘Tori On fẹrẹ de. Oluwa, y’o ti pẹ to Ti ‘Wọ o tun pada? Mà jẹ ki arẹ̀ mu wa Tit’ a o fi ri Ọ. Amin.