- f Ẹ yọ̀ Jesu jọba
‘Nu ọmọ enia
O dá ara tubu
O sọ wọn d’ omnira;
K’ eṣu kọju s’ Ọm’ Ọlọrun,
Lai f’ ọta pè, iṣẹ Rẹ̀ nlọ.
- mf Iṣẹ ti ododo
Otọ, alafia
Fun rọrùn aiye wa,
Yio tàn ka kiri
Keferi, Ju, nwọn o wolẹ̀
Nwọn o jẹjẹ isin yiyẹ.
- f Agbara l’ ọwọ Rẹ̀
Fun àbo ẹni Rẹ̀;
Si aṣẹ giga Rẹ̀
L’ ọpọ o kiyesi,
Ọrun ayọ̀ ri iṣẹ Rẹ̀
Ekuṣu réré gb’ ofin Rẹ̀.
- Irugbin t’ ọrun
O fẹrẹ d’ igi nla;
Abukun wukara
Kò le ṣaitàn kiri;
ff Tit’ Ọlọrun Ọmọ tun wá
Kò lè ṣailọ, Amin! Amin ! Amin.