f Alafia fun Jesu Ọmọ nla Dafidi Ni akoko ti a yan N’ ijọba Rẹ bẹrẹ̀; O de lati tán iya, Lati tú igbekun, Lati mù ẹ̀ṣẹ kuro, Y’o jọba laiṣegbe.
Arab, alarinkiri, Yio wolẹ̀ fun u; Alejo Etiopi, Yio wá w’ogo Rẹ́: Ọkọ̀ okun o pade Pẹlu ọrẹ ìsin; Lati f’ iṣura omi Jọsìn lab’ẹsẹ̀ Rẹ̀.
Ọba yio wolẹ fùn T’ awọn ti turari; Gbogbo orilẹ-ede, Yio si ma yìn i. Ọkọ̀ okun y’o pade, Pẹlu ọrẹ isin; Lati f’ iṣura omi Juba niwaju Rẹ̀.
mf L’ ojojumọ l’ adura Yio ma goke lọ; Ijọba Rẹ̀ y’o mà pọ̀ Ijọba ailopin: Yo’ ṣẹgun gbogbo ọta Y’o joko n ‘itẹ Rẹ̀; Ogo Rẹ̀ yio ma ran Alabukun lailai. Amin.