- f Irawọ wo l’eyi?
Wò b’o ti dara to,
Amọnà awọn keferi
S’ọdọ Ọba ogo.
- Wò awọn amoye
Ti ila-orùn wá;
Nwọn wá fi ori balẹ fun
Jesu Olubukun.
- Imọlẹ ti Ẹmi.
p Má ṣai tan n’ ilu wa;
Fi ọ̀na han wa k’ a le tọ,
Emmanueli wá.
- f Gbogbo irun-malẹ̀,
Ati igba-malẹ̀,
Ti a mbọ n’ ilẹ keferi,
K’ o yàgo fun Jesu.
- mf Ki gbogbo Abọrẹ̀
Ti mbẹ ni Afrika.
Jẹ amoye li otitọ,
Ki nwọn gb’ẹbọ Jesu.
- Baba Ẹlẹda wa,
Ti o fi Jesu hàn
Awọn keferi igbani;
Fi hàn fun wa pẹlu. Amin.