- f Ogo f’Ọlọrun, l’alẹ yi
Fun gbogbo ore imọlẹ.
Ṣọ́ mi, Ọba awọn ọba
Labẹ ojiji ìyẹ Rẹ.
- mp Oluwa, f’ẹ̀ṣẹ mi jì mi,
Nitori Ọmọ Rẹ loni,
K’ emi lè wà l’alafia,
Pẹlu Iwọ ati aiye.
- Kọ mi ki nwà, ki nlè ma wò
Iboji tẹnmen b’ẹni mi;
p Kọ mi ki nkú, ki nle dide
cr Ninu ogo l’ọjọ ‘dajọ.
- mf Jẹ k’ ọkàn mi lè sún le Ọ,
K’ orun didun p’oju mi de;
Orun ti y’o m’ara mi le
Ki nlè sin Ọ li owurọ̀.
- p Bi mo ba dubulẹ laisùn,
F’erò ọrun kun ọkàn mi:
Mà jẹ ki nlala buburu,
Mà jẹ k’ ipa okùn bò mi.
- ff Yin Oluwa gbogbo ẹda,
Ti mbẹ nisalẹ aiye yi:
Ẹ yin loke, ẹda ọrun,
Yin Baba, Ọmọ on Ẹmi. Amin.