- f Jesu, b’ iṣẹ tab’ ìya ni,
Emi o tẹ̀le Ọ!
Bi o ti ṣe, l’emi o ṣe;
B’ o ti wa, l’em’ o wà.
- p Irẹlẹ at’ inu tutù
Ni a ri n’ iwà Rẹ,
Oluwa b’ iwà Rẹ ti ri,
Bẹni ki t’ emi ri.
- f N’ igbẹkele or’ ọfẹ Rẹ
Ni emi o ma lọ;
Emi o tọ ipasẹ Rẹ,
De ‘bugbe Rẹ ọrun. Amin.