- f Bi ‘gba ti Mose gbe ejò
S’ okè li aginju,
Awọn ti ejo ṣan, nwọn sàn:
Nwọn dẹkun lati kú.
- Bẹni lati ọdọ Jesu
N’ imularada nde;
Ẹni t’ o si f’ igbagbọ wo
Yio si ri ‘gbala.
- O wá lati gbe wa dide,
Lati fun wa n’iye,
Igbagbọ mu wa sunmọ Ọ
K’ a má ṣe foya mọ. Amin.