- f Ẹ funpè na kikan,
Ipè ihinrere;
K’ o dún jakè jadò
L’ eti gbogbo ẹda;
ff Ọdun idasilẹ ti de;
Pada, ẹ̀lẹṣẹ, ẹ pada.
- mf Fun ‘pè t’ Ọdagutan
T’ a ti pa ṣ’ ètutu;
cr Jẹ ki agbaiye mọ̀
Agbara ẹjẹ Rẹ̀.
ff Ọdun idasilẹ, &c.
- Ẹnyin ẹerú ẹ̀ṣẹ,
Ẹ sọ ‘ra nyin d’ ọmọ,
Lọwọ Kristi Jesu
Ẹ gba omnira nyin.
ff Ọdun idasilẹ, &c.
- Olori Alufa
L’ Olugbala iṣe;
O fi ‘ra Rẹ̀ rubọ
Arukun, aruda.
ff Ọdun idasilẹ, &c.
- mf Ọkàn alarè, wá,
Simi lara Jesu:
p Onirobinujẹ
Tujuka, si ma yọ̀.
ff Ọdun idasilẹ, &c. Amin.