- mf ‘Wọ Ọmọ ayanfẹ Baba,
Wá lati gbà ilẹ ini,
Ti Baba ti pamọ lailai
Fun ijọba Rẹ ailopin.
- Wá f’ ara Rẹ hàn araiye
Wá ki gbogbo wọn juba Rẹ;
Niwaju Rẹ, gbogbo ahọn
Ni y’o jẹwọ itoye Rẹ.
- Awọn t’ o wà n’ ila-orùn
Ẹgbẹgbẹrun! Nwọn ti pọ to!
Pẹlu awọn t’ ìwọ-orùn
Yio sìn Ọba ologo.
- Gbogbo ariwa, on gusu,
Yio pe orukọ nla Rẹ;
Keferi, ati Ju pẹlu
Nwọn o wá s’ abẹ oyè Rẹ.
- Okunkun ṣú bò wọn mọlẹ;
Ọlọrun Oluwa ‘mọlẹ,
ff Tàn imọlẹ Ihin-rere
Ka gbogbo orilẹ-ede.
- f Yara jẹ ki ‘jọba Rẹ de,
Gbọ́ adura yi, Oluwa;
Ti gbogbo ẹ̀ya at’ ède
Y’o fi mọ̀ Ọ l’Olugbala. Amin.