Hymn 104: How perfect be their feet!

Ese won ti da to!

  1. mf Ẹsẹ wọn ti da to!
    Ti nduro si Sion;
    Awon t’o mu ‘hin ‘gbala wá,
    Awọn t’o f’ayọ̀ hàn.

  2. f Ohùn wọn ti wọ̀ to!
    Ihìn na ti dùn to!
    “Sion, w’ Ọlọrun Ọba rẹ”
    B’o ti ṣẹgun nihin.

  3. Eti wa ti yọ̀ to!
    Lati gbọrọ ayọ̀:
    Wolì, Ọba, ti duro de,
    Nwọn wa, nwọn kò si ri.

  4. Oju wa ti yọ̀ to!
    T’ o ri ‘mọlẹ ọrun;
    Ọba, wolì, nwọn wa titi,
    Nwọn si kú, nwọn kò ri.

  5. ff Oluwa, f’ipà hàn;
    Lori gbogbo aiye;
    Ki gbogbo orilẹ-ède
    W’ Ọba Ọlọrun wọn. Amin.