f Kabiyesi! Isun ‘bukun Ọba, Baba araiye; Keferi r’ore-ọfẹ gbà Nwọn sì nwọ̀ agbala Rẹ: Awa wolẹ̀, awa dupe, A n’ ipò n’nu Ijọ Rẹ; A nf’ igbagbọ wò ogo Rẹ, A nyìn ore-ọfẹ Rẹ.
mf A ti jìna, O si pè wa Sunmọ itẹ mimọ Rẹ; T’ilajà, t’irapada. Amoye, ni ila-orùn, Ri ‘rawọ anu ti ntàn p Ijinlẹ t’o sin latijọ Ijinlẹ ‘fẹ Ọlọrun.
f Kabiyesi: Olugbala, Keferi mu ọrẹ wa: Ni tempili Rẹ l’a nwa Ọ, Jesu Krist’ Oluwa wa; K’ara, ọkàn, at’ ẹmi wa Wà fun iyìn Rẹ nikan: K’ a le jogun ilu Ogo, K’ a si ma yìn Ọ titi. Amin.