- B’ awọn ará igbanì
Ti f’ayọ̀ ri ‘ràwọ na;
Bi nwọn ti f’inu didùn
Tẹle ‘mọlẹ didan rẹ̀;
Bẹ̀, Oluwa Olore
Ni k’a mù wa d’ọdọ Rẹ.
- mf Bi nwọn ti fi ayọ lọ
Si ibujẹ ẹran ná;
Ti nwọn sì wolẹ nibẹ
F’ Ẹni t’ọrun t’aiye mbọ;
Gẹgẹ bẹ mo l’a má yọ̀
Lati wá s’ itẹ anu.
- Bi nwọn ti mu ọrẹ wá
Si ibujẹ ẹran na;
Ba ni k’ awa ma f’ayọ̀
Mimọ t’ẹṣẹ kò bajẹ
Mu ‘ṣura wa gbogbo, wá
Sọdọ Rẹ, Jesu Ọba.
- p Jesu mimọ, pa wa mọ,
L’ọna toro l’ọjọjọ;
cr ‘Gbat’ ohun aiye ba pin,
M’ọkàn wa de ilu, ti
f ‘Ràwọ kò nṣanmọ̀na mọ;
‘Biti nwọn nwò ogo Rẹ.
- Ni ‘lu ọrun mimọ na,
Nwọn kò wá imọlẹ mọ;
‘Wọ l’Orùn rẹ̀ ti ki wọ;
‘Wọ l’ayọ̀ at’ ade rẹ̀;
Nibẹ titi l’ao ma kọ
Halleluya s’Ọba wa. Amin.