Hymn 101: Almighty God, grant that Thy praise

Olorun wa, je k’ iyin Re

  1. mf Ọlọrun wa, jẹ k’ iyìn Rẹ
    Gb’ohùn gbogbo wa kan:
    Ọwọ Rẹ yi ọjọ wa po,
    Ọdun miran si de.

  2. Ẹbọ wa ngoke sọdọ Rẹ,
    Baba, Olore wa:
    Fun anu ọdọdun ti nṣàn
    Lati ọdọ Rẹ wá.

  3. N’nu gbogbo ayida aiye,
    K’anu Rẹ wà sibẹ:
    B’ore Rẹ si wa si ti pọ̀,
    Bẹni k’iyin wa pọ̀.

  4. N’nu gbogbo ayida aiye,
    A nri aniyàn Rẹ;
    Jọwọ, jẹ k’anu Rẹ ‘kanna
    Bukun ọdún titun.

  5. B’ayọ̀ ba si wà, k’ayọ̀ na
    Fà wa si ọdọ Rẹ;
    B’ìya ni, awa o kọrin
    B’ibukun Rẹ pelu. Amin.