Hymn 100: The heavenly controller

Alakoso ti orun

  1. mf Alakoso ti ọrun,
    Alànu at’ Ọlọgbon;
    Igbà mi mbẹ lọwọ Rẹ,
    Opin gbogbo l’aṣẹ Rẹ.

  2. Aṣẹ Rẹ l’o da aiye
    Ati ibi mi pẹlu;
    Obi, ilẹ, on igba;
    Nipa Rẹ ni gbogbo wọn.

  3. f Igb’aisàn, on ilera,
    Igbà iṣẹ on ọrọ;
    Igbà ‘danwò, ibinu,
    Igbà ‘ṣẹgun, iranwọ.

  4. Igba iridi Eṣu
    Igba ‘tọ ‘fẹ Jesu wọ̀,
    Nwọn o wá, nwọn o si lọ,
    B’Ọre wa ọrun ti fe.

  5. ff Iwọ Olore-ọfẹ,
    ‘Wọ ni mo f’ẹmi mi fun,
    Emi jẹwọ ifẹ Rẹ,
    Emi tẹriba fun Ọ. Amin.