- mp Baba mi gbọ temi!
‘Wọ ni alabò mi,
Ma sunmọ mi titi:
Oninure julọ!
- Jesu Oluwa mi,
Iye at’ ogo mi,
K’ ìgba na yara de,
Ti ngo de ọdọ Rẹ.
- p Olutunu julọ,
‘Wọ ti ngbe inu mi,
‘Wọ t’o mọ̀ aini mi,
Fà mi, k’o si gbà mi.
- mp Mimọ, mimọ, mimọ,
Ḿá fi mi silẹ lai;
p Ṣe mi n’ ibùgbe Rẹ,
Tirẹ nikan lailai. Amin.