APA I
- f Ji, ọkàn mi, ba orùn ji,
Mura si iṣẹ òjọ rẹ;
Má ṣe ilọra, ji kùtu,
K’ o san gbèse ẹbọ orọ̀
- mp Rò gbogb’ ọjọ t’ o fi ṣòfo;
Bẹrẹ si rere ‘se loni;
Kiyes’ ìrìn rẹ laiye yi;
K’o sì mura d’ọjọ nla nì.
- mf Gbà ninu imolẹ ọrun,
Si tanmọlẹ nà f’ẹlomi;
Jẹ ki ogo Ọlọrun rẹ
Hàn n’nu ìwa at’ise re.
- f Ji, gbọn’ra nù, ‘wọ ọkàn mi,
Yàn ipò rẹ larin Angel,
Awọn ti nwọn nkọrin iyìn
Ni gbogbo oru s’ Ọba wa. Amin.
APA II - Mo ji, mo ji, ogun ọrun,
K’ emi l’agbara bi ti nyin;
K’ emi ba le lo ọjọ mi
Fun iyìn Olugbala mi.
- mf Ogo fun Enit’ o ṣọ mi,
T’o tù mi lara loj’ orun;
Oluwa ijọ mo ba ku,
Ji mi s’aiye ainipẹkun.
- p Oluwa mo tún ẹ̀jẹ́ jẹ,
Tu ẹ̀sẹ ka b’ ìri orọ;
Ṣọ akọronu mi oni,
Si f’Ẹmi Rẹ kun inu mì
- cr Ọrọ at’ iṣe mi oni
Ki nwọn le ri bi ẹkọ Rẹ;
f K’ emi si f’ ipà mi gbogbo
Ṣiṣẹ rere fun Ogo Rẹ. Amin.