Anglican Hymnal
O God of Bethel, by whose hand
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 98: O God of Bethel, by whose hand
Olorun Betel, eniti
Hymn:
98
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Odun Titun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ọlọrun Bẹtẹl, ẹniti
O mbọ́ awọn Tirẹ;
Ẹnit’ o mu baba wa là
Ọjọ aiye won ja.
p
A mu ẹjẹ́, at’ ẹ̀bẹ wa
Wá iwaju ‘tẹ Rẹ,
Ọlọrun awọn baba wa,
f
Ma jẹ Ọlọrun wa.
Ninu idamu aiye yi,
Ma tọju wa;
Fun wa ni onjẹ ojọ wa,
At’ aṣọ t’o yẹ wa.
Na, ojiji ‘yẹ Rẹ bò wa,
Tit’ ajò wa o pin,
Ati ni ‘bugbe Baba wa,
Ọkàn wa o simi.
Iru ibukun bi eyi,
L’a mberè lọwọ Rẹ:
Iwọ o jẹ Ọlọrun wa
At’ ipin wa lailai. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites