Anglican Hymnal
Days and moments quickly flying
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 91: Days and moments quickly flying
Ojo ati akoko nlo
Hymn:
91
Meter:
P.M (Irregular)
Season:
Opin Odun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ọjọ ati akoko nlọ
Nwọn nsún wa s’ eti ‘boji;
p
Awa fẹrẹ dubulẹ na,
Ninu ihò ‘busun wa.
mf
Jesu, ‘wọ Olurapada
Ji ọkàn t’ o ku s’ẹ̀ṣẹ;
cr
Ji gbogbo ọkan ti ntogbe,
Lati yàn ipa iyè.
mp
Bi akoko ti nsunmọle,
Jẹ k’ a rò ‘bi to a nlọ;
Bi lati r’ayọ̀ ailopin,
pp
Tabi egbé ailopin.
mf
Aiye wa nlọ!
pp
Ikú de tan.
mf
Jesu, ṣọ́ wa
pp
Tit’ O fi de.
K’ a ba Ọ gbe
p
K’ a ba Ọ kú,
f
K’ a ba Ọ jọba titi lailai.
mp
Aiye wa nkọja b’ojiji
O si nfò lọ bi ‘kuku;
cr
Fun gbogbo ọun t’o kọja
Dariji wa, mu wa gbọn.
mf
Kọ wa lati kà ọjọ wa,
Lati ba ẹ̀ṣẹ wa jà;
K’ a má ṣarẹ̀, k’ a má togbe
Tit’ a o fi ri ‘simi.
f
Gbogbo wa fẹrẹ̀ duro na
Niwaju itẹ ‘dajọ;
ff
Jesu ‘wọ t’o ṣẹgun iku
Fi wa s’apa ọtun Rẹ.
mf
Aiye wa nlọ!
pp
Ikú de tan:
Olugbala!
mf
Jọ pa wa mọ.
K’a ba Ọ gbe,
pp
K’ a ba Ọ kú,
f
K’ a ba Ọ jọba titi lailai. Amin
« Back to Hymn List
View Favourites