Anglican Hymnal
Christians lift your voice in praises
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 86: Christians lift your voice in praises
Onigbagbo, e bu sayo !
Hymn:
86
Meter:
8.7.8.7.8.7
Season:
Ojo Ibi Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
ff
Onigbagbọ, ẹ bu sayọ !
Ọjọ nla l’ eyi fun wa;
K’ ọrun f’ ayọ kọrin kikan,
K’ igbo at’ ọ̀dun gberin .
ff
Ẹ ho! ẹ yọ̀ !Ẹ ho! ẹ yọ̀!
Okun at’ odò gbogbo.
f
Ẹ jùmọ yọ̀, gbogbo ẹda,
Laiye yi ati lọrun;
f
Ki gbogbo ohun laiye
Nilẹ lokè yìn Jesu.
Ẹ f’ ogo fun, Ẹ f’ ogo fun,
Ọba nla t’a bi loni!
ff
Gb’ ohùn nyin ga, “Ọmọ Afrik”
Ẹnyin iran Yoruba;
Ké ‘ Hosanna! ‘ l’ ohùn goro
Jakè-jadò ilẹ wa.
K’ ọba gbogbo , K’ ọba gbogbo
Juba Jesu Ọba wa.
f
Ẹ damusò! ẹ damusò!
ff
Ẹ ho yè! K’ ẹ sì ma yọ̀:
Itẹgun èṣu fọ́ wàyí,
“ Iru-ọmobirin” de!
Halleluya ! Halleluya!
Olurapada, Ọba.
Ẹ gb’ ohùn nyin ga, Serafu,
Kerubu, lẹba ìtẹ;
Angẹli at’ ẹnyin mimo,
Pẹlu gbogb’ ogun ọrun,
f
Ẹ ba wa yọ̀ ! Ẹ ba wa yọ̀ !
Ọdun idasilẹ de.
Mẹtalọkan , Ẹni Mimọ,
Baba, Olutunu,
Ẹmi Mimọ, Olutunu,
Jesu, Olurapada,
Gbà iyìn wa, Gbà iyìn wa,
‘Wọ nikan l’ogo yẹ fun. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites