Anglican Hymnal
Songs of praise the angels sang
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 82: Songs of praise the angels sang
’Gba Jehofah da aiye
Hymn:
82
Meter:
7.7.7.7
Season:
Ojo Ibi Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
‘Gba Jehofah da aiye;
cr
‘Gbat’ o sọrọ̀ t’ o si ṣẹ,
Awọn Angẹli nkọrin
ff
Halleluya gb’ ọrun kan.
mf
Orin ‘yìn l’ a kọ l’ orọ̀
Gbat’ a bi Olugbala;
cr
Orin ‘yìn ni a si kọ
Nigbat’ o digbekùn lọ.
p
‘Gbat’ aiye y’o kọja lọ
Iyìn o gb’ ọjọ na kan;
‘Gbat’ a o d’ aiye titun,
Orin iyin l’ a o kọ.
Awa o ba dakẹ bi
Titi jọba na o de?
Bẹkọ ! Ijọ o ma kọ
Orin mimọ́ at’ iyìn.
Enia mimọ́ l’ aiye,
Nf’ ayọ̀ kọrin iyìn na;
Nipa ‘gbagbọ ni nwọn nkọ,
Bi nwọn o ti kọ l’ oke.
p
Nigba ẹmí o ba pin
Orin ni o ṣẹgun ‘ku;
f
Ninu ayọ̀ ailopin
Nwọn o ma kọrin titi. Amin
« Back to Hymn List
View Favourites