Anglican Hymnal
The happy day at last has dawned
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 79: The happy day at last has dawned
Ojo ayo nlanla na de
Hymn:
79
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ojo Ibi Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọjọ ayọ̀ nlanla na de,
Eyi t’ araiye ti nreti;
cr
Nigbat’ Olugbala w’aiye
Nigbat’ a bi ninu ara.
f
Oluṣagutan ni pápá
Bi nwọn ti nṣọ agutan wọn,
Ni ihin ayọ na kọ̀ bá.
Ihin bibi Olugbala.
Angel iranṣẹ Oluwa
L’ a ran si wọn, alabukun,
Pẹlu ogo t’ o tan julọ,
Lati sọ ihin ayọ̀ yi.
mp
Gidigidi l’ ẹ̀ru bà wọn,
Fun ajeji iran nla yi:
f
“Má bẹru” l’ ọ̀rọ iyanju
T’ o t’ ẹnu Angẹli na wá.
A bi Olugbala loni,
Kristi Oluwa aiye ni;
N’ ilu nla Dafidi l’ o wà,
p
N’ ibujẹ ẹran l’ a tẹ si.
f
“Ogo fun Ọlọrun” l’ orin
Ti enia y’o kọ s’ ọrun;
Fun ifẹ Rẹ̀ laini opin,
T’ o mu alafia w’ aiye. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites