Anglican Hymnal
All ye Christians burst into joy
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 78: All ye Christians burst into joy
Onigbagbo, e bu s’ ayo
Hymn:
78
Meter:
8.7.8.7.8.7
Season:
Ojo Ibi Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Onigbagbọ, ẹ bu s’ayọ̀,
Ọjọ nla l’eyi fun wa;
Ẹ gbọ bi awọn Angẹli
Ti nf’ ogo fun Ọlọfun;
Alafia, Alafia
Ni fun gbogbo enia.
ff
Ki gbogbo aiye ho f’ayọ̀,
K’ a f’ ogo fun Ọlọrun,
Ọmọ bibi Rẹ̀ l’ o fun wa
mf
T’ a bi ninu Wundia;
Ẹn’ Iyanu, Ẹn’ Iyanu
Ni Ọmọ t’a bi loni.
Ninu gbogbo rudurudu,
On ibi t’ o kun aiye,
Ninu idamu nla ẹ̀ṣẹ
L’ Ọm’Ọlọrun wà gbà wa;
Olugbimọ, Olugbimọ,
Alade Alafia.
f
Ọlọrun Olodumare
L’ a bi, bi ọmọ titun;
Baba! Ení aiyeraiye
L’ o di alakoso wa:
ff
E bú s’ayọ, Ẹ bu’ s’ ayò,
Ọmọ Dafidi jọba.
p
O wà gbà wa lọwọ ẹṣẹ,
O wà d’ onigbọwọ wa
Lati fọ itẹgun Eṣu
A ṣe ni Ọba ogo;
f
Ẹ kù ayọ̀, Ẹ kù ayọ̀,
A gbà wa lọwọ ikú. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites