Anglican Hymnal
The day of judgement, day of fright
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 73: The day of judgement, day of fright
Ojo dajo, ojo eru!
Hymn:
73
Meter:
8.7.8.7.4.7
Season:
Bibo Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọjọ dajọ, ọjọ ẹru!
Gbọ́ bi ipè ti ndún to!
O ju ẹ̀gbarun ará lọ
O si nmì gbogbo aiye.
p
Bi ẹ̀sùn na
Y’ o ti damu ẹlẹṣẹ!
mf
Wò Onidajọ l’àwọ wa,
T’ o wọ ogo nla l’aṣọ
Gbogbo wọn ti nwo ọnà Rẹ̀,
‘Gbana ni nwọn o ma yọ̀.
p
Olugbala,
Jẹwọ mi ni ijọ na.
f
Ni pipè Rẹ̀ okù o jí
Lat’ okun, ilẹ, s’ iye;
Gbogbo ipa aiye y’o mì,
Nwọn o salọ loju Re.
p
Alaironu,
Yio ha ti ri fun ọ?
Eṣu ti ntàn ọ nisiyi,
Iwo mà ṣe gbọ tirẹ̀,
‘Gbati ọ̀rọ yi kọja tan,
Y’o rì ọ ninu iná;
p
Iwọ ronu
Ipò rẹ ninu ina!
Labẹ ipọnju, at’ẹgan,
K’eyi gba ọ n’ iyanju;
Ọjọ Ọlorun mbọ tete,
‘Gbana ẹkùn y’o d’ ayọ,
f
A o ṣẹgun
Gbati aiye ba gbina. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites