Anglican Hymnal
Lo! He comes with clouds descending
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 70: Lo! He comes with clouds descending
Wo ! Oluwa l’ awosanma
Hymn:
70
Meter:
irregular
Season:
Bibo Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Wo! Oluwa l’ awọ̀sanmà,
O mbọ l’ogo, l’ ọla Rẹ̀.
Ẹni t’ a pa tun ẹlẹṣẹ
Mbọ pẹlu Angeli Rẹ̀;
ff
Halleluya!
Halleluya! Amin .
Gbogbo ẹda, wá wò Jesu,
Aṣọ ogo l’ a wọ̀ fun;
p
Awọn t’ o gan, awọn t’o pa,
T’ o nkan mọ agbelebu;
pp
Nwọn o sọkun
Bi nwọn ba ri Oluwa.
Erekuṣu, okun, oke,
Ọrun, aiye, a fò lọ
Awọn t’ o kọ a dà wọn rú,
Nigbati nwọn gbohun Rẹ̀,
pp
Wá s’ idajọ
Wa s’ idajọ, wá kalọ!
Irapada t’ a ti nreti,
O de pẹlu ogo nla;
Awọn ti a gàn pẹlu Rẹ̀
Yio pade Rẹ̀ loj’ ọrun!
ff
Halleluya
Ọjọ Olugbala de. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites