Anglican Hymnal

Rejoice, the Lord is King:

Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.

Hymn 68: Rejoice, the Lord is King:

Oluwa ni Oba

Hymn: 68
Meter: 6.6.6.6.8.8
Season: Bibo Jesu
Add Favourite
  1. f Oluwa ni Ọba;
    Ẹ bọ Oluwa nyin:
    Ẹni kiku, ṣọpẹ,
    Y’ ayò ‘ṣẹgun titi
    ff Gb’ ọkàn at’ ohùn nyin soke
    “Ẹ yọ,” mo si tun wi, “Ẹ yọ̀.”

  2. Olugbala jọba,
    Ọlọrun otitọ;
    ‘Gbat’ o wẹ ‘ṣẹ wa nù,
    O goke lọ joko;
    ff Gb’ ọkàn at’ ohùn, &c

  3. O mbẹ lọdọ Baba,
    Titi gbogbo ọta,
    Yio tẹri wọn ba,
    Nipa aṣẹ Tirẹ̀.
    ff Gb’ ọkàn at’ ohùn, &c

  4. Yọ̀ n’ ireti ogo
    p Onidajọ mbọ̀ wa;
    Lati mu ‘ranṣẹ Rẹ̀
    Lọ ‘le aiyeraiye.
    A fẹ gbohun Angẹl nla na,
    ff Ipè y’o dun wipe, “Ẹ yo,” Amin.