Anglican Hymnal
We love all the earthly stock below
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 581: We love all the earthly stock below
Awa fe ohun aiye yi
Hymn:
581
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Oniruru
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Awa fẹ ohun aiye yi,
Nwọn dara l’oju wa;
A fẹ k’a duro pẹ titi,
Laifi wọn silẹ lọ.
Nitori kini a nṣe bẹ?
Aiye kan wà loke;
Nibẹ l’ ẹ̀ṣẹ on buburu
Ati ewu kò si.
Aiye t’o wà loke ọrun,
Awa iba jẹ mọ!
Ayọ̀, ifẹ, inu rere,
Gbogbo rẹ̀ wà nibẹ.
p
Ikú, o wà ni aiye yi;
Kò si loke ọrun;
Enia Ọlọrun wà mbẹ̀,
Ni ayè, ni aikú.
K’a ba ọ̀na ti Jesu lọ,
Eyi t’O là fun wa;
ff
Sibi rere, sibi ‘simi,
cr
S’ ile Ọlọrun wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites