Anglican Hymnal
Salvation though, Salvation though
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 580: Salvation though, Salvation though
Igbala ni, igbala ni
Hymn:
580
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Oniruru
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Igbala ni, igbala ni
Awa ẹlẹṣẹ nfẹ;
Nitori ninu buburu
T’a ṣe l’ awa nṣègbé.
Iṣẹ ọwọ wa ti a nṣe,
O nwi nigbagbogbo
mp
Pe, igbala kò si nibẹ,
Iṣẹ kò lè gba ni.
Awa nṣẹbọ, awa nrubọ,
A nkọrin, a si njo;
Ṣugbọn a kò ri igbala
Ninu gbogbo wọnyi.
Nibo ni igbala gbe wà?
Fi han ni, if han ni:
B’o wa lokè, bi isalẹ,
B’o ba mọ̀, wi fun wa.
Jesu ni ṣe Olugbala,
Jesu l‘Oluwa wa;
Igbala wà li ọwọ Rẹ̀;
Fun awa ẹlẹṣẹ.
f
Wá nisisiyi, wá tọrọ,
Ifẹ wà ninu Rẹ̀;
Ẹnyin ti o buru l’O npè pe;
ff
Ẹ wá gba igbala. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites