Anglican Hymnal
We lay down this foundation, Lord
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 575: We lay down this foundation, Lord
A fi ipile yi le’ le
Hymn:
575
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Kiko tabi sisi Ile Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
A fi ipilẹ̀ yi le ‘lẹ̀,
Ni orukọ Rẹ Oluwa,
Awa mbẹ̀ ọ, Oluwa wa.
Ma tọju ibi mimọ́ yi.
Gba enia Rẹ ba nwá Ọ,
T’ẹlẹṣẹ nwá Ọ, n’ ile yi,
Gbọ́, Ọlọrun lat’ ọrun wa,
F’ ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, Ọlọrun.
‘Gb’ awọn Alufa ba nwasu
Ihinrere ti Ọmọ Rẹ;
Ni orukọ Rẹ̀, Oluwa,
Ma ṣiṣẹ iyanu nla Rẹ.
‘Gb’ awọn ọmọde ba si nkọ
f
Hosèanna si Ọba wọn;
cr
Ki Angẹl ba wọn kọ pẹlu,
K’ ọrun at’ aiye jọ gberin.
Jehofah o ha ba ni gbe,
Ni aiye buburu wa yi?
Jesu o ha jẹ Ọba wa,
Ẹmi o ha simi nihin?
f
Má jẹ ki ogo Rẹ kuro
Ninu ile ti a nkọ yi;
Ṣe ‘jọba Rẹ ni ọkàn wa,
Si tẹ itẹ Rẹ sinu wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites