Anglican Hymnal
God doth see all the work we do
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 569: God doth see all the work we do
Ise gbogbo ti awa nse
Hymn:
569
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Imo- Ohun gbogbo Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Iṣẹ gbogbo ti awa nṣe,
Ni Ọlọrun ti ri;
Erò gbogbo t’o wà ninu,
Ni Ọlọrun si mọ̀.
mp
A kò le f’ẹṣẹ wa pamọ,
Gbogbo wọn l’O ti mọ̀:
A npurọ, a ntàn ‘ra wa jẹ,
B’ a rò pe kò mọ̀ wọn.
Ohun gbogbo hàn ni gbangba,
Ni oju Ọlọrun;
Okunkun ati imọlẹ,
Si ri bakanna fun.
f
Ọlọrun, jẹ k’a ranti pe,
Oju rẹ si ri wa;
Si jẹ ke awa k’o bẹ̀ru
Lati dẹṣẹ si Ọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites