Anglican Hymnal
Praise, my soul, the King of heaven
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 568: Praise, my soul, the King of heaven
Okan mi, yin Oba orun
Hymn:
568
Meter:
8.7.8.7.4.7
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọkàn mi, yìn Ọba ọrun,
Mu ọrẹ wa s’ọdọ Rẹ̀;
mp
‘Wọ t’a wòsan t’a dariji,
cr
Tal’ a ba ha yìn bi Rẹ̀?
f
Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Yin Ọba ainipẹkun.
mf
Yin, fun anu t’O ti fihàn,
F’awọn baba ‘nu pọnju;
Yìn I, ọkan nà ni titi,
O lọra lati binu:
f
Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Ologo n’nu otitọ.
p
Bi baba ni O ntọju wa,
O si mọ̀ ailera wa;
Jẹjẹ l’o ngbe wa l’apa Rẹ̀,
O gbà wa lọwọ ọ̀ta;
f
Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Anu rẹ̀ yi aiye ka.
A ngbà b’ itàná eweko,
T’ afẹfẹ nfẹ, t’o si nrọ;
p
‘Gbati a nwà, ti a si nkú,
Ọlọrun wà bakannà;
f
Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Ọba alainipẹkun.
ff
Angẹl, ẹ jumọ ba wa bọ,
Ẹnyin nri lojukoju;
Orùn, oṣupa, ẹ wolẹ̀,
Ati gbogbo agbaiye.
Ẹ ba wa yìn, Ẹ ba wa yìn
Ọlọrun Olotitọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites