Anglican Hymnal
Let us sing to the Son of God
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 562: Let us sing to the Son of God
A korin s’ Omo Olorun
Hymn:
562
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
A kọrin s’Ọmọ Ọlọrun,
p
Ọdagutan t’a pa;
Ti ọrun ati aiye mbọ,
T’O yẹ lati jọba.
Si Ọ l’ awọn Angẹli nke,
L’ ẹkùn gbogbo ọrun;
p
“Mimọ́, mimọ́, mim’ Ọlọrun,
T’ ogo, at’ ọm’ ogun.”
f
Ijọ Rẹ li aiye dapọ,
di
Lati ma kepe Ọ;
Didan Ọlanla Ọlọrun,
T’ O l’agbara gbogbo.
Larin wọn ni gbogbo wa nfẹ
Lati yìn ẹjẹ Rẹ;
Jọba l’ aiye ati l’ ọrun,
‘Wọ Ọmọ Ọlọrun. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites