Anglican Hymnal
All hail the power of Jesus' name!
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 561: All hail the power of Jesus' name!
Gbogbo aiye, gbe Jesu ga
Hymn:
561
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Gbogbo aiye, gbe Jesu ga,
di
Angẹl, ẹ wolẹ fun;
cr
Ẹ mu ade Ọba Rẹ̀ wa,
Ṣe l’Ọba awọn ọba.
mf
Ẹ ṣe l’Ọba, ẹnyin Martyr,
Ti npè ni pẹpẹ Rẹ̀;
cr
Gbe gbongbo-igi Jesse ga,
f
Ṣe l’Ọba awọn oba.
mf
Ẹnyin iru-ọmọ Israẹl,
Ti a ti rapadà;
cr
Ẹ ki Ẹnit’ o gbà nyin là,
f
Ṣe l’Ọba awọn oba.
p
Gbogbo enia ẹlẹṣẹ,
Ranti ‘banujẹ nyin;
cr
Ẹ tẹ́ ‘kogun nyin s’ẹsẹ Rẹ̀,
f
Ṣe l’Ọba awọn oba.
ff
Ki gbogbo orilẹ-ede,
Ni gbogbo agbaiye;
Ki nwọn ki, “Kabiyesilẹ,”
Ṣe l’Ọba awọn oba.
mf
A ba le pẹl’ awọn t’ọrun,
Lati ma juba Rẹ̀;
cr
K’a ba le jọ jumọ kọrin,
ff
Ṣe l’Ọba awọn oba. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites