Anglican Hymnal
Oh worship the King, all glorious above!
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 560: Oh worship the King, all glorious above!
E wole f’Oba, Ologo julo
Hymn:
560
Meter:
10.10.11.11
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ẹ wolẹ̀ f’Ọba, Ologo julọ,
Ẹ kọrin ipa ati ifẹ Rẹ̀;
Alabo wa ni, at’ Ẹni Igbani,
O ngbe ‘nu ogo, Ẹlẹrù ni iyìn.
Ẹ sọ t’ipa Rẹ̀, ẹ sọ t’ore Rẹ̀;
‘Mọlẹ l’aṣọ Rẹ̀, kọ̀bi Rẹ̀, ọrun,
cr
Ará ti nsán ni kẹ̀kẹ́ ‘binu Rẹ̀ jẹ́;
Ipa ọna Rẹ́ ni a kò si le mọ̀.
mf
Aiye yi pẹlu ẹ̀kún ‘yanu rẹ̀,
Ọlọrun, agbara Rẹ l’o dá wọn;
O fi idi rẹ́ mulẹ, kò si le yí,
O si f’okun ṣe aṣọ igunwà Rẹ̀.
cr
Ẹnu ha lè sṣ ti itọju Rẹ̀?
Ninu afẹfẹ, ninu, imọlẹ;
di
Itọju Rẹ̀ wà nin’ odo t’o nṣan,
p
O si wà ninu ìri ati òjo.
mp
Awa erupẹ, aw’ alailera,
cr
‘Wọ l’a gbẹkẹle, O kì o dà ni;
Anu Rẹ̀ rọnu, o si le de opin,
f
Ẹlẹda, Alabo, Olugbala wa.
ff
‘Wọ Alagbara, Onifẹ Julọ,
B’awọn angẹli ti nyìn Ọ l’oke,
di
Bẹ l’awa ẹda Rẹ, niwọn t’a le ṣe,
cr
A o ma juba Rẹ, a o ma yìn Ọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites