Anglican Hymnal
O! Thou our priceless Redeemer
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 558: O! Thou our priceless Redeemer
Wo, owon Olurapada
Hymn:
558
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
‘Wọ, ọ̀wọn Olurapada,
A fẹ ma gburo Rẹ;
Kò s’ orin bi orukọ Rẹ,
T’o lè dun t’ abọ rẹ̀.
mf
A ! a ba lè ma gbohùn Rẹ!
L’ anu sọrọ si wa;
Nin’ Alufa wa l’a o yọ̀,
Mẹlksedẹk giga.
Jesu ni y’o ṣe orin wa,
Nigbat’ a wà l’aiye;
A o kọrin ifẹ Jesu,
‘Gba nkan gbogbo bajẹ.
Nigba ‘ba yọ sokè lọhun
Pẹlu ‘jọ, ẹni Rẹ;
ff
‘Gbana a o kọrin kikan,
Krist ni y’o j’ orin wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites