Anglican Hymnal
Through all the changing scenes of life
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 555: Through all the changing scenes of life
N’nu gbogbo ayida aiye
Hymn:
555
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
N’nu gbogbo ayida aiye,
Ayọ on wahala;
cr
Iyin Ọlọrun ni y’o ma
Wà l’ẹnu mi titi.
f
Gbe Oluwa ga pẹlu mi,
Ba mi gb’Okọ Rẹ̀ ga;
p
N’nu wahala, ‘gbà mo kepe,
cr
O si yọ mi kuro.
f
Ogun Ọlọrun wà yika
Ibugbe olotọ;
Ẹniti o ba gbẹkẹle,
Yio si ri ‘gbàla.
mf
Sá dán ifẹ Rẹ̀ wó lẹkan,
Gbana ‘wọ o mọ̀ pe,
Awọn t’o di otọ Rẹ̀ mú
Nikan l’ ẹniẹ’bùkún.
cr
Ẹ bẹru Rẹ̀, ẹnyin mimọ,
Ẹru miràn kò si;
Sa jẹ ki ‘sìn Rẹ j’ayọ̀ nyin,
On y’o ma tọju nyin. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites