Anglican Hymnal
Awake, and sing the song
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 553: Awake, and sing the song
Ji! ko orin Mose
Hymn:
553
Meter:
S.M (6.6.8.6)
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ji ! kọ orin Mose
Ati t’Ọd’agutan;
Ji gbogbo ọkàn at’ ahọn,
Ki nwọn yin Oluwa.
p
Kọrin ti ikù rẹ̀,
f
Kọrin ajinde Rẹ̀;
cr
Kọrin b’ O ti mbẹbẹ loke,
F’ ẹ̀ṣẹ awọn t’O rù.
mf
Ẹnyin èro l’ọnà,
Ẹ kọrin b’ ẹ ti nlọ;
ff
Ẹ yọ̀ ninu Ọdagutan,
Ninu Kristi Ọba.
Ẹ fẹ gbọ k’O wipe,
“Alabukun, ẹ wá”
On fẹrẹ̀ pè nyin lọ kurò,
K’O mu Tirẹ̀ lọ ‘le.
cr
Nibẹ l’a o kọrin
Iyìn Rẹ̀ ailopin,
f
Ọrun y’o si gbe ‘rin Mose,
Ati t’Ọd’agutan. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites